Omo Olufon Ade,Omo erujeje adugbo.
Omo oloko dudu idi oro,Omo Ajanaku padi oro busubusu.
Omo olesin l’eekan baba tomide,osokanlu ab’esin p’owole’rin, oni bi’ku ‘obapa aban,ti nkan o s’oowa,yioje oruko t’eyin nje bo d’ola.
Omo afingba ina mosadoyin, Omo ija ob’ejo ayoogbo,enun l’oka fi soro.
Omo apere abe lemo wupo Ope n Idoo wale,sukusuku Eja ni yoo sin won l’enun.
Adabanija! Adabanija!!Adabanija okunrin Osokanlu baba Efundoyin.
Adabanija okunrin gban’bata, gban’bata, gban’bata kosubu, Adabanija okunrin ogun.
Eni ija koba niipera’re l’okunrin.